PINNU LATI TĘLĘ OHUN NAA

Olukowe: Ayo Awe-Joseph

Onitumo: Dr Olubusola Afolayan 

A dupę lọwọ Ọlọrun fun ohun to ti bęrę ni ile ijọsin IGNITE CHURCH lasiko aawę ati adura olọjọ meje ti a ṣęṣę pari. 

Adura wa lasiko aawę naa ję adura Oba Dafidi to fi wi pe: OLUWA FUN MI NI ỌKAN TUNTUN 

Aaya iṣę wa ti bę silę, o ti bę are ni, a ti ṣetan lati ba Ọlọrun rin ni gbogbo ọna lọdun 2020 titi de opin aye. 

Ninu akọsilę ti a fi sita gbęyin ni mo ti sọ nipa bi ohun Ọlọrun ṣe ba mi sọrọ pe asiko mi lati maa gbe igbe aye ęṣę ti dopin 

Lati ọjọ kęrindinlọgbọn, oṣu kęsan an, ọdun 1992 ni mo ti n tęlę ohun to pe mi naa. 

Pęlu inu didun ati ọpę si Ọlọrun ni mo fi gba ipe naa ni eyi to ti fihan mi pe ko si ohun miran ti mo le yan laye ati lati de ọrun bikoṣe lati gbọ “Ohun Naa” 

Ohun Naa ti tọ mi sọna ninu bi mo ṣe n rin irinajo aye mi, yiyan iṣę oojọ mi, pipade iyawo ti mo fę sile ati lori kikọ idile mi. 

IṢẸ ỌMỌLĘYIN KRISTI: 

Mo ranti ijọ ti wọn kọkọ pe mi si lęyin ti mo ronupiwada kuro ninu aiṣedeede mi, nibi ti inu mi ko fi bęę dun pupọ. 

Ijọ ęlęmi igbalode ko wọpọ lasiko naa rara, mo n sinru ilu ni ile iṣę ologun Naijiria ti ęka ọmọ ogun 82 Division ni Enugu ni mo lọ nibi ti awọn bii ida aadọrun ninu ọgọrun awọn eeyan n sun lasiko ti alakoso ijọ wọn n waasu lori ęrọ redio. 

Nitori pe mo ję ęni to maa n ṣawada to fęran orin pupọ, mo sọ fun ara mi pe “ibi yii kii ṣe aaye mi” fun idi eyi mo kọ lati pada lọ si ile ijọsin naa. 

Nigba to ya mo bęrę si ni ni oungbę lati gbọ ohun naa sii ati pe mo ṣetan lati gbe igbesę to yę lori ohunkohun ti ohun naa ba pa laṣę fun mi lati ṣe nitori pe mo mọ riri ohun naa to n dari aye mi. 

Nigba to ya, mo fi iṣę silę nile iṣę ologun lęyin ti mo woye pe ko si ibi to dara to fun mi lati kọ ękọ sii gęgę bii ọmọlęyin Kristi ki n le dagbasoke sii ninu ęmi bo ti yę. 

Eyi ję ki n ko pada wa si ilu Eko nibi ti ohun naa ti dari mi lati lọ si ijọ Victory Christian Church nibi ti mo ti gbadun iwaasu oloogbe Bisọobu Hafford Anayo Iloputaife. 

Biṣọobu yii ję ęni ọwọ nitootọ ati pe mo gbadun orin ati awọn ilana eto ijọsin wọn daradara. 

Ijọ yii ni ogbontarigi onkọrin ęmi ọmọ Amerika ni, Ron Kenoly kọkọ wa si ni Naijiria. Inu mi si dun pupọ lati tę duuru ‘Trombone’ fun un lasiko to n kọrin “Ancient of Days” nigba naa. 

Ojoojumọ ni mo n dagba ninu ęmi sii bayii ti mo si n gbọ Ohun Naa daadaa lasiko yii. 

Bayii mo ti mọ itumọ ohun naa sii daadaa pe “Arugbo ọjọ” ni orukọ ohun naa to ti n dari mi titi mo fi de ijọ ti mo ti ni oore-ọfę lati kọ siwaju sii lori bi a ṣe n di ọmọlęyin Kristi nitootọ. 

A maa tęsiwaju lori eyi ni ọla… 

Fun Ibeere; igniteinternationalchurch.org

Ero ibanisoro; 08121662594

Leave a comment