OLUWA FUN MI NI ỌKAN ẸRAN ARA 

Olukowe: Ayo Awe-Joseph 

Onitumo: Dr Olubusola Afolayan

Esekięli 11:19 sọ pe: 

Emi yoo fun wọn ni ọkan tuntun, Maa paarọ ọkan okuta kuro ni ara wọn lati fi ọkan ęran ara dipo rę. 

Iwe Matteu13: 1-23 ni Jesu ti sọ owe nipa afurugbin kan ati eso rę pęlu ilę ti wọn bọ si ni eyi to fi ṣe akawe iru ọkan ęda eniyan. Oriṣi męrin ni ilę naa to duro fun ọkan eniyan ję ninu owe naa.  

Ẹba ọna- Eyi duro fun ọkan ti oye ọrọ Ọlọrun ko ye bi a ti ṣe waasu ọrọ ijọba Ọlọrun fun un. 

2. Ori Okuta- Eyi ję ęni to gbọ ọrọ ijọba Ọlọrun to gba a pęlu ayọ Ṣugbọn lęyin ti inunibini dide sii, o ṣubu nitori pe ọrọ naa ko ni gbongbo ni ọkan rę. 

3. Aarin Ẹgun- Eyi ję ęni to gbọ ọrọ Ọlọrun Ṣugbọn ti wahala ati ironu aye fun ọrọ naa pa ninu ọkan rę nipasę ọna atila to n wa kiri. 

4. Ilę rere- Eyi duro fun ọkan ti o yę ki a maa beere lọwọ Ọlọrun. O ję ilędu to ni igbagbọ ati Ifę Ọlọrun, O bęru, o si ṣetan lati gbọran si Ọlọrun lęnu nipasę titęle aṣę rę nigba gbogbo. 

"Ni ọjọ kan naa ni Jesu ti ile jade, o si joko ni eti okun 

Ọpọlọpọ eniyan pọ si ọdọ rę, to bęę ti o fi bọ sinu ọkọ, o joko; gbogbo eniyan si joko leti okun. 

O si fi owe ba wọn sọrọ ohun pupọ, o wi pe, woo Afurungbin kan jade lọ lati lọ fun irugbin 

Bi o si ti n funirugbin naa, dię bọ si eba-ọna, awọn ęyę si wa, wọn ṣaa ję 

Dię bọ si ori apata nibi ti ko si erupę pupọ, wọn si sọ jade lọgan, nitori ti wọn ko ni ijinlę. 

Nigba ti oorun si goke, wọn jona, nitori ti wọn ko ni gbongbo, wọn si gbę 

Dię si bọ si aarin ęgun, nigba ti ęgun si dagba soke, o fun wọn pa 

Ṣugbọn omiran bọ si ilę rere, o si so eso, omiran ọgọrọọrun, omiran ọgọgọọta, omiran ọgbọọgbọn. 

Ẹni ti o ba ni eti kọ gbọ” 

Ọkan wa gbọdọ wa ni ilę ọlọra to ję ilędu ki o le gba eso ọrọ Ọlọrun ti yoo fun wa ni eso riri awọn ileri Ọlọrun gba. 

Adura wa lasiko yii ni ki OLUWA yọ ọkan okuta kuro ni aya mi, ko fun mi ni ọkan ęran ara ti yoo maa so eso pupọ to dara. 

Fun Ibeere: igniteinternationalchurch.org

Ero Ibanisoro: 08121662594

Leave a comment