NINI OYE KIKUN NIPA AYE TUNTUN

Olukowe: Ayo Awe-Joseph 

Onitumo: Dr Olubusola Afolayan 

Ni ibęrę ifilọle atęjade Kingdom Blog wa lọdun yii, a sọ pe Ọba Dafidi ni a fę lo gęgę bii awokọṣe lori ọrọ to nii ṣe pęlu ironupiwada nitootọ ki eeyan le ba Ọlọrun rin bi o ti yę (Jọwọ kọkọ ka atęjade to ṣaaju eyi) 

Lọdun 2020, o wu wa ki ijọba Ọlọrun tęsiwaju ninu aye wa ati ninu ębi wa, ninu okowo wa ati ni orilę-ede gbogbo. Asiko ti to ki a yapa kuro ninu ilana ęsin ti ko bi eso rere, ti ko mu inu awọn olujọsin dun, ti ko fun awọn olujọsin ni ireti lati mọ sii nipasę ijọba Ọlọrun. 

A ri bi Ọba Dafidi ṣe bębę fun ọkan tuntun to n duro sinsin lęyin to ṣe agbere pęlu Baaṣeba to si tun ṣe iku pa Uriah to ję ọkan lara awọn ọmọ ogun rę (Orin Dafidi 51: 10 ati 2 Samuęli 11: 1-27). 

Eyi ni a ti fi ṣe akori idanilękọọ wa ni Kingdom Blog ni eyi ti a maa ṣayęwo bi eniyan ṣe le ba Ọlọrun laja pęlu ironupiwada kikun lęsęęsę. 

Ohun akọkọ ni pe ki a kọkọ pinnu lati kọ awọn iwa wa atijọ silę ki a gba lati bęrę si ni gbe igbe aye ọtun to wa ninu oore ọfę igbala Jesu Kristi. 

 Igbesę to ku ni lati maa kọ ofin rę si ookan aya ęni gęgę bi Heberu10: 16 ṣe sọ pe: Eyi ni majęmu ti emi yoo ba wọn da lęyin igba naa ni Oluwa wi. Emi yoo fi ofin mi si aya wọn, emi yoo kọọ si ookan aya wọn. 

A o maa ṣagbeyęwo igbesę ati ilana to yę lori bi eeyan yoo ṣe ni ajọṣepọ to dan mọran pęlu Ọlọrun bi o ṣe n kọ ofin rę si ookan aya wa lati isin yii lọ ninu awọn atęjade ti a o maa gbe jade lori Kingdom Blog 

Ẹ ję ki a ranti pe ọkan eniyan ni alakoso gbogbo iwa eniyan nitori pe ọkan ni o n bi ero rere ati ero to n ba nkan ję yatọ si pe ọkan ni o n gba ifitonileti gbogbo yala eyi to dara tabi eyi ti ko dara. 

Atunṣe ọkan ęni ni ofin tabi ilana akọkọ ti eniyan ni lati kọkọ tęlę ni kete ti o ba bęrę si ni ba Ọlọrun rin gęgę bi iwe Owe 4: 23 ṣe sọ. 

ILANA 1 

Iwe Owe 4: 23 ni: Ju gbogbo ohun ipamọ, Pa aya rę mọ, nitori pe lati inu rę wa ni orisun iye. 

Kini ipamọ tumọ si? 

Ipamọ tumọ si pe ki eeyan ma ję ki ọwọ awọn ti ko yę tę ohun kan tabi ki wọn ri ohun naa. 

Roo lọkan rę pe o ni ile kan to kun fun goolu ti ęgbęlęgbę owo dọla ilę America, bawo ni o ṣe maa daabo bo wọn ni ipamọ? 

Ọkan eniyan ṣe iyebiye ju iṣura alumọọni gbogbo lọ ninu aye. O ję ile ti o kun fun iṣura olowo iyebiye ti ko ni onka nibiti o ti yę ki eniyan maa jọba lori ohun gbogbo bi Gęnęsiisi 1: 27 – 28 ṣe laa kalę. 

Ọlọrun lo ṣęda ọkan eniyan pęlu iṣę pipe bii oun funrarę, eyi ko ję ko yani lęnu pe aṣę akọkọ ti Ọlọrun pa fun Adamu ni pe ko maa toju ọgba Edeni. 

Ọkan ję orisun fun iye nitori pe o ni agbara lati mi eemi sinu ni eyi ti gbogbo agbaye si n wadii. Irufę ero daadaa tabi buruku ati erongba ati aba ti eeyan n ro wa lati inu ọkan eniyan. 

Gęnęsiisi 6: 17 sọ nipa bi Oluwa ti ri bi ero ọkan eniyan ṣe buru to ninu aye nigba gbogbo ni eyi to ję ki Oluwa kabamọ pe oun da eniyan si aye ti ọkan rę si baję gidgidi. Koda, awọn Angęli to ti subu lọrun lo anfani ipo ọkan eniyan yii. 

Fun idi eyi, o yę ki a pa ajọṣepọ wa pęlu Ọlọrun mọ daradara lęyin ti a ba ti ba Ọlọrun laja ki a si daabo to yę bo awọn isura to ti fun wa. 

Ni Gęnęsiisi 4: 7:  Ọlọrun kilọ fun Kaini, akọbi-kunrin Adamu pe ęṣę ba ni ęnu ọna, lọdọ rę ni ifę rę yoo maa fa si, iwọ yoo si maa ṣe alakoso rę. 

Kaini, ọmọ Adamu gbọ ikilọ lọdọ Ọlọrun lati daabo bo ọkan rę bi o ti yę kuro lọwọ awọn ero buruku Ṣugbọn o kuna lati ṣe eyi titi ti ęmi ibinu ati owu jiję fi bori ọkan rę to fi pa Abeli aburo rę. 

Ohun akọkọ to ṣe Pataki si onigbagbo ni lati daabo bo ọkan rę kuro lọwọ awọn ęmi ati ero buruku ki a si ni oye kikun lori gbigbe igbe aye tuntun. 

A o maa tęsiwaju….  

Fun ibeere: igniteinternationalchurch@gmail.com

Ero ibanisoro:08121662594

Leave a comment