ỌNA LATI FI ỌLỌRUN SI OOKAN AYA RẸ  SHEMA NAA: 

Olukowe: Ayo Awe-Joseph

Onitumo: Dr Olubusola Afolayan

Deuteronomi 6: 4-9 sọ ni kikun nipa aṣę Ọlọrun pe: 

Gbọ Israeli, Oluwa Ọlọrun wa, Oluwa kan ni 

Ki iwọ ki o si fi gbogbo aya rę, ati gbogbo ọkan rę, ati gbogbo agbara rę fę Oluwa Ọlọrun rę 

Ati ọrọ wọnyii, ti mo palaṣę fun ọ li oni, ki o maa wa ni aya rę 

Ki iwọ ki o si maa fi wọn kọ awọn ọmọ rę gidigidi, Ki iwọ ki o si maa fi wọn ṣe ọrọ sọ nigba ti iwọ ba joko ninu ile rę, ati nigba ti iwọ ba n rin ni ọna, ati nigba ti iwọ ba dubulę, ati nigba ti iwọ ba dide 

Ki iwọ ki o si sọ wọn mọ ọwọ rę fun ami, ki wọn ko si maa ṣe ọja-igbaju niwaju rę 

Ki iwọ ko si kọ wọn si ara opo ile rę ati sara ilękun ọna-ode rę 

Shema naa ję aṣę si awọn eniyan Ọlọrun lati gbe Ọlọrun ga si ipo rę laarin ookan aya wọn.   

Iṣę alaṣepe ni ọkan eniyan ję. Ọlọrun ṣe e lati maa ronu nigba gbogbo bii ęrọ amunawa fun iroyin. 

Gęnęsisi 1:26 fi ye wa pe aworan Ọlọrun ni eniyan ję ati pe a da ọkan eniyan lati maa ṣęda nkan miran pęlu ọgbọn Ọlọrun ni. 

Ọlọrun da ọkan eniyan lati fęran Ọlọrun rę ki o maa gbe niwaju Ọlọrun nigba gbogbo, ki o si maa gbadun iṣęda Ọlọrun. 

Adamu fi iṣe han nipa aṣę iṣęda ti Ọlọrun fun ọkan eniyan nipa fifun gbogbo eranko ti Ọlọrun da ni orukọ to wu u (Gęnęsiisi 2:19) 

Eniyan sọ ogo rę nu, o si bęrę si ni gbe ninu ewu ni kete ti eniyan ṣe lodi si aṣę Ọlọrun ninu ọgba Edeni nipasę jiję eso igi imọ nipa rere ati buburu. 

Ṣaaju jiję eso yii, ọpọlọ Adamu n ṣiṣę bi o ti yę ti o si n ba ęmi Ọlọrun rin papọ ni eyi to padanu to si ję ki ęru ba a nitori o ni oun wa ni ihoho (Gęnęsiisi 3:10) 

Ni iwe Matteu 5:28 Jesu wi pe: Ṣugbọn Mo sọ fun yin wi pe ęnikęni to ba wo obinrin pęlu ifękufę ti ṣe agbere ninu ọkan rę 

Ohun ti oju ri, ti eti gbọ, ti ọwọ kan, ti ara kan, ti imu gbọ oorun lo n lọ taara lati ba ọkan sọrọ ni eyi ti o n ṣe lodi si aṣę Ọlọrun nigba miran bii ti asiko Adamu ni Gęnęsiisi 3:10 

Ọlọrun fę ki ọkan ęda eniyan gba iṣakoso aye, ki awon ero ọkan eniyan maa da bi opo waya ina mọnamọna to n dari irin eniyan lati apa A lọ si apa B ki opọlọ eniyan si maa mu erongba ọkan eniyan ṣe. 

Eyi ję ki Ọlọrun fun eniyan ni agbara lati ṣęda ohun to wuu bi apęrę itan ile iṣọ Babeli to wa ninu iwe Gęnęsiisi 11: 1-9. 

Apęęrę ohun ti ero ọkan eniyan le ṣe si ibi ni aye ode oni ti onikaluku wa le tete ranti ni iṣęlę ibi to ṣęlę lorilę-ede America ni ọjọ kọkanla, oṣu kęsan an, ọdun 2011 nibi ti ọpọ ęmi ti sọnu. 

Ṣe iwọ naa ti wa ri ohun to ję ki Ọlọrun sọ ni Gęnęsiisi 6: 5-6 pe oun kabamọ pe oun da eniyan lęyin to ti ri gbogbo iwa ika inu ęda adarihurun. 

Ohun ti a ka ni ęsę akori wa ni Deuteronomi naa ni Jesu Kristi sọ ninu iwe Matteu 22: 37 pe ki gbogbo awon to fę Ọlọrun pada si aaye iṣęda wọn lati ibęrę ni eyi to yę ko hande lati ara ero ọkan wa ati ihuwasi wa pęlu ibęru Ọlọrun ni ookan aya wa. 

Ọlọrun Aṣęda da ọkan eniyan ki o le maa so eso iwa rere kaakiri agbaye ninu ọrọ eniyan ati iṣę rę. Idi ni yii to fi ni ki a kọ awon ọmọ wa ni ilana Oun nigba gbogbo ni eyi ti a le pe ni Shama naa lasiko yii. 

Iwe Owe 4: 23 ni ki o pa ọkan rę mọ gidigidi nitori ninu rę ni orisun ohun gbogbo ti n san wa sita. 

Jọwọ pinnu lati mojuto ero ọkan re nitori pe oun lo maa dari ọwọ re, ohun ti o maa fi si ęnu, ohun ti o maa fi ara kan, ohun ti oju re maa wo ati ohun ti eti rę maa gbọ pęlu ohun ti imu rę maa gbọ oorun rę.  

Apęrę miran ni a ri pelu ihuwasi awọn ọmọ Heberu męta: Ṣadraki, Miṣaęli ati Abędnego. Wọn kọ lati fori balę fun ere wura ti Ọba Nębukadnesari gbe kalę. 

Loju ęsę ni wọn ti fi ipinnu wọn han pe ohun ti ọkan awọn sọ fun awọn nipasę ibęru Ọlọrun ni awọn maa ṣe ni eyi to pada yọri si ęri nla fun wọn ni ilę ajoji. 

Lai naani ina ileru ti Ọba fę sọ wọn si, wọn gbọran si aṣe Ọlọrun ni igbęyin Ọlọrun fi ara rę han ni alagbara, gbogbo ilę ajoji naa si wariri fun iṣę nla ti Oluwa ṣe nipasę awọn ọmọ Heberu męta wọnyii.

Leave a comment