Olukowe: Ayo Awe-Joseph
Onitumo: Dr Olubusola Afolayan
Ni igba kan ti a si wa ni ile iwe, awọn iṣę kan wa ti o le fun wa dię lati mo gęgę bi akekọọ, Ṣugbọn ọna abayọ ni lati ka a ni akọsori fun igba dię titi o o fi pari idanwo olukọ rę lori iṣę naa ki o le ṣe aṣeyege.
Nitootọ, o ṣeęṣe ki o ṣe aṣeyege ninu iṣę naa Ṣugbọn o ko ni ni imọ kikun lori ękọ naa bi o ti yę.
Bęę gęgę ni awọn miran n ṣe pęlu Ọlọrun lati ri esi adura wọn gba, Ṣugbọn Mo layọ lati sọ fun un yin loni wi pe ỌLỌRUN KII ṢE AKỌSORI.
Ęmi ni Ọlọrun, o fę ki o mọ oun, ki o fęran oun, ki o si bọwọ fun un. O da eniyan ni aworan ara rę ni eyi to tumọ si pe ęsin ko ṣe alaye Ọlọrun to ni ękunręrę.
Lęękọọkan, wọn maa n pe Ọlọrun bii alejo wa sibi awọn akanṣe eto bii: “Ibapade lati oke wa” ati bęę bęę lọ ni eyi ti yoo ti fun awọn eniyan dię ni iwosan, owo, ọmọ, igbega ati awọn nkan miran ti wọn yoo si gbagbọ pe Ọlọrun yoo pada si aaye rę to ti wa titi di ọjọ miran ti wọn yoo tun ni akanṣe eto miran.
Eyi ję ọkan lara awọn aṣiṣe to ti bi awọn eso aini iwa bi Ọlọrun ni agbaye lati ọpọlọpọ ọdun ṣęyin. Awọn eniyan n wa Ọlọrun nitori ohun ti wọn fę gba lọwọ rę kii ṣe nitori pe wọn fę mọ iru ęni ti Ọlọrun funrarę ję.
Wọn ti sọ Ọlọrun di Akọsori ti wọn yoo jo fun, ti wọn yoo kọ orin iyin si Gęgę bi awọn kan ti sọ fun wọn lati ri ohun ti wọn fę gba lọwọ rę.
Si iru awọn wọnyii, orin iyin ati ębọ ọrę loriṣiiriṣii ni yoo mu Ọlọrun dawọn lohun lasiko yii. Eyi ko ję ko yani lęnu orisii irufę orin, ijo to n kọnilominu, ati ọna iyin ti ko fogo fun Ọlọrun to kun igboro bayii ti awọn kan n tan ara wọn pe: Ki ęnikęni ma da awọn lęjọ, nitori pe Oba Dafidi naa jo irufę ijo to wuu.
Matteu 15:8-9 ni: “Awọn eniyan yii n fi ete wọn bu ọla fun mi Ṣugbọn ọkan wọn jina si mi. Ijọsin wọn ni ko ję itęwọgba ati ękọ wọn to ję ofin eniyan lasan.
Ọlọrun ko fę ję alejo ni aye lasan ti yoo maa wa ṣe abęwo sile aye nigba kọọkan Ṣugbọn o fę maa gbe inu ọkan awọn eniyan biliọnu meje to wa nile aye ni.
Kete too ba ti silękun ọkan rę fun Ọlọrun, ti o n gbe igbe aye mimọ, ti o n bu ọla fun un ni yoo fi aye rę ṣe ibujoko rę bii ọrun titi aye.
O wu Ọlọrun ko ba ọ rin irinajo aye rę lojoojumọ, nigba gbogbo ninu ọrọ, ninu ero ati ninu ipinnu reę laisi ęṣę ninu aye rę.
Ọlọrun ko fę dabi akọsori tabi onidan ti yoo kan maa yọju lasiko adura, orin iyin, ijo jijo, aawę gbigba, tabi lasiko akanṣe eto rę nitori Johannu 9: 31 ni pe kii gbọ adura elęṣę rara bikoṣe adura olootọ.
Orin Dafidi 50: 21-23 fi ye wa pe O wu Ọlọrun lati maa dari gbogbo igbesę wa gęgę bi ęnikọọkan, idile, ijọba ati orilę-ede; lęyin eyi ni inu rę yoo dun si ębọ ọrę wa, ijo wa, orin iyin wa, aawę ati adura wa.
Ęnikęni to ba ru ębọ iyin, o n yin mi logo; ati ęni ti o ba mu ọrọ rę tọ li Emi o fi igbala Ọlọrun han fun
Ki Ifę Ọlọrun ṣę ni aye wa bi a ti n gbiyanju lati mọ ọ si i lorukọ Jesu
Fun ifitonileti lękunręrę, kọwe si: igniteinternationalchurch@gmail.com
Ero Ibanisoro: 08121662594