Olukowe: Ayo Awe-Joseph
Onitumo: Dr Olubusola Afolayan
“Iroyin Ayọ” kii ṣe ọrọ to ṣe ajoji si gbogbo wa paapaa nipa awọn ohun ini wa. Ko si ęni ti ko wu lati maa gba iroyin ayọ lojoojumọ.
Oriṣiiriṣii nkan ni a n so pọ mọ iroyin ayọ bii: ayọ ọmọ tuntun, igbeyawo, aṣeyọri iwe ęri tuntun, rira ọkọ tabi ile tuntun, tabi iro atęjiṣę lori ęrọ alagbeka rę pe owo kan wọ inu banki rę.
Ni ti awa ni Kingdom Blog, Iroyin Ayọ fun wa ni pe a ti lu aluyọ lori kikọ awọn iroyin wa lori itakun agbaye wa lọ si tuntun ti a ṣęṣę ṣi ni eyi to fun wa laaye lati dara loriṣiriṣi ki a le tun ję ki o ręwa sii.
Koda, iroyin Ayọ ni pe idi ti a ko fi si lori ayelujara fun asiko dię pada yọri si rere.
Loni IROYIN Ayọ to tobi julọ ni mo muwa ninu atęjade Kingdom Blog ti ọtę yii. O ṣeeṣe ki a ti maa gbọ ọrọ yii nile ijọsin wa Ṣugbọn ko ma ti i ni itumọ kikun fun wa.
Kini Iroyin Ayọ Gęgę bi Bibeli ṣe Laa Kalę?
Gęgę bii obi, ko si igba ti mo ba awọn ọmọ mi wi ti n ko ki n mọọ lara bi o ṣe dun awọn ọmọ ti mo n ba wi paapaa julọ ti ibawi naa ba mu ijiya pupọ lọwọ.
Ọpọ igba ni ibawi naa pęlu ijiya to tọ fun wọn maa n ję ki wọn ṣalai ręrin, ki wọn dękun ere ṣiṣe ninu ile tabi ki inu wọn ma dun lasiko naa Ṣugbọn gęgę bii baba, mo maa n ba wọn ṣere, titi wọn a fi ṣere ninu ile pada.
Ọpọ igba ni igbesę ipadabọsipo awọn ọmọ ti a bawi yii maa n mu ayipada ọkan dani ti wọn yoo si maa huwa to dara ju ti atęyinwa lọ.
O maa n ję iroyin ayọ nigba ti a ba pari ę, ti ajoṣepọ wa si tun n dan mọran si i.
Kini mo kọ gęgę bii Baba?
Mo kọ gbogbo ihuwasi awọn ọmọ mi eyi ti ko ba tęle ilana tabi ofin
Itan ęda eniyan ko yatọ si eyi ti mo sapejuwe tęlę rara. Adamu ati Efa to ję obi iran eniyan kọ eti ikun si ofin Ọlọrun, eyi si ję ki o le wọn kuro ninu ọgba Edeni nibi ti wọn ti ni ajọṣepọ to dara pęlu Ọlọrun tęlę ti ohun gbogbo wa ni akunwọ silę fun wọn ni ibęrę pępę dida aye.
Gbogbo ęda ọmọ eniyan jogun aigbọran awọn mejeeji ni eyi ti wọn fi kuna ogo Ọlọrun.
Kii ṣe ohun kekere lati kuro niwaju baba ęni nitori pe ęni naa yoo padanu ojurere ati awọn anfani miran ti baba naa ni fun iru ọmọ bęę.
Apejuwe ti mo le ṣe fun bi Adamu ṣe kuro niwaju Ọlọrun ni pe o dabi ọmọ to wa lati ile ọla to jade ni owurọ Ṣugbọn ti ko ṣeeṣe fun un lati pada wa si ile ni alę lati wa sun.
O n lọ ṣiṣę oojọ rę Ṣugbọn ko le ri aaye wọnu ile mọ lojoojumọ lo maa rin kiri bii alarinkiri ęda ti o n sun ita. O di alainile lori ti o si le ṣe alabapade oriṣiriṣi ewu.
Gęnęsisi 3:24: “Bęęli O le okunrin naa jade, O si fi awọn Kerubu ati ina de iha ila-oorun Edeni ti n jo kaakiri, lati maa sọ ọna igi iye naa”.
Pipada lọ sile (lọdọ Ọlọrun) ko nii ṣe pęlu iye owo ti eniyan ni tabi ti ko ni; Gęgę bi abuda ęja ṣe ję lati maa gbe ninu omi naa ni a da eniyan lati maa wa niwaju Ọlọrun.
Lati igba ti Adamu ti kuna ninu ọgba Edeni yii ni ęda eniyan ti n wa gbogbo ọna lati wa ojutu si iṣoro naa. Ọpọ olọwọ ni ọkan wọn ko bale ti inu wọn ko dun ti wọn si n fi igba gbogbo wa ibugbe tuntun Ṣugbọn ti ko si alaafia nibę. Bęę naa ni awọn talaka naa ko ni isinmi nitori iṣe ati oṣi to n ba wọn finra.
Igbe aye otitọ lo n fun ęni ni alaafia niwaju Ọlọrun; Bibeli sọ pe: O si wi fun wọn pe, kiyesara ki ę si maa sọra nitori ojukokoro; nitori igbesi aye eniyan ki i duro nipa ohun ini to pọ (Luku 12 : 15).
Bakan naa ni Heberu 4: 1-2 sọ pe: Nitori naa e ję ki a bęru, bi a ti fi ileri ati wọ inu isinmi rę silę fun wa, ki ęnikęni ninu yin ki o ma dabi pe o ti kuna rę; A ti waasu ihinrere fun wa gęgę bi a ti ṣe fun awọn naa. Ṣugbọn, ọrọ ti wọn gbọ ko ṣe wọn ni rere, nitori ti ko dapọ mọ igbagbọ ninu awọn ti o gbọ ọ.
Fun idi eyi, awa naa ti gba IROYIN AYỌ to ję IHINRERE naa.
Kini Iroyin Ayọ ti a gba naa?
Ihinrere naa ni pe a ti ba wa laja pęlu Ọlọrun nipasę ęję Jesu Kristi to ta silę. Nitori naa, a ti dariji wa, a ko nilo lati wa nita mọ Ṣugbọn ki a wọle sinu ile niwaju Ọlọrun.
Efesu 2: 1 sọ pe: Ęyin ti ku nipaṣe ęṣę yin, Ọlọrun wa ti sọ yin di iye ninu Kristi nitori pe o dari gbogbo ęṣę ji yin, o si pa akọsile irekọja wa re nigba ti o kan wọn mọ agbelebu.
Jesu Kristi san ębọ idiyele to tobi julọ nigba to ku fun eniyan lati pari iṣę imupadabọsipo lęyin ti Adamu ti ṣubu.
Mo fę tete sọ nibi pe ęję ni ębọ idiyele fun aigbọran Adamu ki a le dariji eniyan; idi niyi ti Jesu ọmọ Ọlọrun ṣe wa lati ọrun si aye lati san ębọ idiyele to tobi naa fun ipari ija laarin eniyan pada sọdọ Ọlọrun. Jesu lo ṣe atọna eniyan lati di ọmọ pada niwaju Ọlọrun.
O ti le ni ęgbęrun meji ọdun ṣęyin ti Jesu ti ku ni eyi to ti ję atọna ti ọpọ ti fi ję ęni itęwọgba niwaju Ọlọrun
Iroyin Ayọ ninu itan eniyan ni pe a ti sọ ojurere wa nu tęlę niwaju Ọlọrun Ṣugbọn a ti ri irapada gba bayii sinu aye tuntun to kun fun ifę niwaju Ọlọrun to ję baba wa.
IROYIN AYỌ yii naa ni IHINRERE.
Iroyin Ayọ naa ni Ihinrere gęgę bi a ti ti ọwọ Matteu, Marku, Luku ati Johannu kọ ọ silę pe: Ṣugbọn iye awọn to ba gba a gbọ, awọn ni o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn naa ti wọn ba gba orukọ rę gbọ (Johannu 1:12).
Ki Ọlọrun mu ijọba rę de ninu aye wa, ki ifę rę ṣe!
Fun ibeere, ę kan si: -igniteinternationalchurch@gmail.com
Ero ibanisoro; 08121662594