Olukowe: Ayo Awe-Joseph
Onitumo: Dr Olubusola Afolayan
Ti Oluwa ni ilę, ati ękun rę, aye ati ohun gbogbo to tędo sinu rę. Nitori pe o fidi ę sọlę sori okun, o si gbee kalę sori ọwọn isan omi (Orin Dafidi 24: 1-2)
Myles Munroe sọ pe: “Nigba ti awọn eeyan ko ba mọ idi nkan, ko si ki aṣilo ma wa”.
Ọpọ igba ni awọn eeyan miran n rin ninu aye lai beere ibeere pe: Tani mi?; Idi wo ni mo ṣe wa nibi?
Ninu atęjade Kingdom Blog ti ọtę yii, a n ṣe agbeyęwo ohun to yę kọ ję idi ti eeyan ṣe wa si aye gęgę bii ILANA AKỌSILẸ ęni to da eeyan.
Iwe Orin Dafidi sin wa ni gbęrę ipakọ lori ęni to ni aye ati bi a ṣe da aye.
Orin Dafidi 24: 1 ni pe:
O fi idi aye sọlę lori okun ati pe o gbe aye kalę sori ọwọn iṣan omi.
Iwe Orin Dafidi sọ bi Ọlọrun ṣe ṣeda aye ti o si gbe e kale fun eniyan lati maa ṣe akoso lee lori.
Iwoye wa sọ fun wa pe omi lo maa fęę bo gbogbo aye ki Ọlọrun to paṣę pe ki ilę wa nigba ti o ko omi jọ si oju kan to di ọpọlọpọ odo ati okun bii ti Arctic, Atlantic, Pacific, Southern ati Indian lęyin ti o ti paṣę fun wọn ki wọn ko ma ṣan kọja bebe wọn.
Jobu 38: 8-11sọ nipa ibeere nla pe:
Ta ni o fi ilekun se omi okun mọ nigba ti o ya jade bi ęni to ti inu tu jade wa?
Tabi nigba ti mo fi awọ sanmọ ṣe aṣọ rę, ati okunkun ṣiṣu ṣe ọja igbanu rę? Nigba ti mo paṣę ipinnu mi fun un ti mo si ṣe bebe ilękun rę?
Ti mo si wi pe nihin yii ni iwọ yoo de, ki o ma si rekọja rę, nihin yii ni igberaga riru omi rę yoo gbe duro mọ?
Akọsilę iwe Owe 8: 22-31 ṣe apejuwe Ọgbọn ti Ọlọrun fi ṣęda aye gęgę bii ọdọmọde lęgbę Ọlọrun nigba ti o n ṣęda aye pe:
“Oluwa pęṣę emi ọgbọn ni ipilęṣę iwa rę, ṣaaju iṣę rę atijọ
A ti yan mi lati ayeraye, lati ipilęṣę, tabi ki aye ki o to wa
Nigba ti ọgbun ko si, a ti bi mi, nigba ti ko si orisun ti o kun fun omi pupọ.
Ki a to fi idi awọn oke nla sọlę, ṣaaju awọn oke ni a ti bi mi
Nigba ti ko tii da aye tabi pętęlę tabi ori erupę aye
Nigba ti o n ṣe ipilę awọn iṣan omi, emi wa nibę, nigba ti o n fi oṣuwọn ayika le oju ọgbun.
Nigba ti o sọ awọ sanmọ lọjọ soke, nigba ti o fi agbara fun orisun ibu
Nigba ti o fi aṣę rę fun okun, ki omi rę ki o ma ṣe kọja ęnu rę; ati ofin rę fun ipilę aye
Nigba naa ni emi wa lọdọ rę bi oniṣę, emi si ję didun inu rę lojoojumọ, emi n yọ nigba gbogbo niwaju rę
Emi n yọ bi ibi itedo aye rę; didun inu mi si wa sipa awọn ọmọ eniyan”.
Pęlu ęri to kun lękunręrę yii ni a ti ri bi Ọlọrun ṣe da aye, eyi si yę ko ję ki gbogbo wa gba pe: TI OLUWA NI AYE ati ohun gbogbo to teędo sinu rę.
Gęnęsiisi 1: 31fi idi ę mulę pe Ọlọrun ni ohun gbogbo ti oun da DARA lęyin to pari iṣę dida aye tan.
Ni kete ti Ọlọrun pari iṣę dida aye DIDARA TO RẸWA tan ni o gbe e le Adamu ati Efa lọwọ bi ọmọ tuntun jojolo.
Gęnęsisi 1:27-28 ni:
Ọlọrun si da eniyan ni aworan ara rę, ni aworan ara rę ni Ọlọrun da wọn takọ tabo. Ọlọrun si sure fun wọn pe “E maa bi sii, ki ę si maa rę sii, ki ę si gbilę, ki eę si ṣe ikawo rę, ki ę si maa jọba lori rę.
Kete ti Adamu ṣe aigbọran si Ọlọrun nipa jiję eso naa ni ohun gbogbo yipada. Lati igba naa ni awọn ọmọ ti eniyan n bi ti buru ti wọn n gbe ninu ewu. Awọn oniṣę ibi lo kun inu aye bayii ni eyi ti inu Ọlọrun ko dun si.
Gęnęsisi 6: 5-7 ni:
Ọlọrun si rii pe iwa buburu eniyan di pupọ ni aye, ati pe gbogbo ero ọkan re ję kikida ibi lojoojumọ.
Inu Oluwa si baję nitori ti o da eniyan si aye, o si dun un de ọkan rę (Duro ki o ronu lori koko yii daadaa).
Igba gbogbo ti mo ba ka ęsę bibeli oke yii ni inu mi maa n baję gidi si abamọ Ọlọrun lori dida emi ati iwọ.
Ko si onile kankan nile aye to maa fę ki ayalegbe wo ile oun tabi ko ba a ję lai le e kuro nile rę.
Ni Gęnęsisi 6: 1-8 ni Ọlọrun ti le awọn olugbe aye kuro nipa fifi omi pa aye rę nigba aye Noa ati ębi rę.
Aye gbọdọ pada si dida rę ati bi o ṣe ręwa lati igba iṣęda ti eniyan ba fę ki inu Ọlọrun dun si aye bii ti ibęrę.
Idi ni yii ti Jesu fi wa si aye lati da eniyan pada si ipo rę iṣaaju ni eyi to mu ki Jesu kọ wa bi a ti n gbadura pe ki IJỌBA RẸ DE NI AYE BI WỌN TI N ṢE NI ỌRUN.
Adura yii ni o ti di ADURA OLUWA bayii
Ọna abayọ si iṣoro to n koju eniyan laye to ṣęlę lataari iwa ibaję eniyan ko ju pe ki Ijọba Ọlọrun de si aye lọ.
Fun ibeere: igniteinternationalchurch@gmail.com
Ero ibanisoro:08121662594