Olukowe: Ayo Awe-Joseph
Onitumo: Dr Olubusola Afolayan
Ohun iyalenu lo ję bi aye ṣe ti yipada to lati nkan bii ogun ọdun ṣęyin paapaa pęlu gbigbe ifitonileti jade lọna igbalode lasiko yii.
Imo ijinlę ęrọ ti yi gbogbo ọna ibanisọrọ pada lai yọ ọna itaja, ọna ifowopamọ, idanilaraya, iwe kika, irinajo ati bęę bęę lọ.
Ojoojumọ ni gbogbo nkan n yi pada ti ọrọ di ọrọ ọmọ ti aye n bi ti aye n pọn lasiko yii.
Bi apęrę, lasiko idagbasoke iṣę ati okowo, Bibeli pọ sii de ibi pe kii ṣe awọn alufaa nikan lo n nii lọwọ mọ. Eyi waye lataari ęrọ itęwe ti wọn sawari re lasiko naa.
Bayii to ję asiko ayelujara, iṣeju aaya ti ina fi n rin ni nkan fi n yi pada.
Awọn eeyan ko ni suuru mo bii ti igba kan lati tete ri esi gba.
Laye igba kan ọpọ ero lo maa to nile ifowopamọ ki wọn to le ri owo gba ni banki Ṣugbọn bayii, ęrọ alagbeka ati ęrọ to n pọ owo ti sọ aye dęrọ kaakiri. Koda, o le fi ọpọlọpọ owo ranṣę kaakiri agbaye lati iyara rę ti o ti n jęun lai bọ sita rara.
Laye atijọ ti o ba fę rinrinajo afę lọ si orilę-ede kan tabi omiran, o maa nilo awọn oṣiṣę to n mojuto irinajo afę lati ba ọ wa ile itura ti wa a de si, ba ę yanju ọrọ tikęęti irinna ti wa a fi wọ ọkọ ofurufu ati bęę bęę lọ, Ṣugbọn ko ri bęę mọ ni asiko yii.
O le ṣeto gbogbo igbesę yii lati inu iyara rę kaakiri agbaye nipa lilo ęrọ ayelujara lori ęrọ alagbeka rę lasiko igbalode yii.
Koda, o le ṣeto ọkọ ero UBER ti wọn n kero lati papakọ ofurufu ati bęę bęę lọ.
Mo kọkọ beere idi ti Ọlọrun ṣe tun fę ki a da ijọ Ignite International Christian Church laduru gbogbo ijọ to ti kunlę lasiko yii kaakiri lọwọ Olọrun.
Gęgę bi iṣe ęnikęni to ba ṣęṣę fę da ijọ silę, eeyan maa nilo ilę tabi ile lọjọọjọ Aiku, eeyan maa nilo ohun eelo, owo oṣu awọn oṣiṣę atawọn inawo nlanla miran. O fęrę dabii ohun ti ko le ṣeeṣe nitori pe nibo ni mo ti fę ri owo awọn nkan wọnyii?
Lęyin eyi ni OLUWA si mi loju inu paapaa lori lilo ayelujara lasiko igbalode yii ati awọn nkan ti a le ṣe lasiko yii han fun araye lati inu ile ęni.
Iṣe Awọn Apọsteli 1: 18 sọ pe:
ęyin yoo gba agbara nigba ti ęmi mimọ ba bale yin; E o maa ṣe ęlęri mi ni Jerusalemu, ni gbogbo Judea ati Samaria, ati ni gbogbo opin aye.
Bawo ni a ṣe fę waasu de opin aye?
Ka sọ pe eeyan 100, 000 lo n jọsin nile ijọsin wa, a si maa ni ęgbęlęgbę biliọnu eniyan ti wọn si n duro de iwaasu ijọba Ọlọrun
Koko kan ti a ti fi idi ę mulę ni pe lati igba ti a ti bęrę Kingdom Blog yii la ti n gba esi lojoojumọ lori ni atęjade naa ṣe n bukun awọn eniyan, ti wọn n yi igbe aye wọn pada si rere nipa biba Ọlọrun laja lęyin ti wọn ba ti ka Kingdom Blog tan.
ĘMI NI ỌLỌRUN
Koko ti a fę gbe yęwo lọtę yii muni ranti itan Obinrin ara Samaria ti Jesu pade nidi Kanga ninu iwe Johannu 4: 23-24.
Igba naa n bọ, a ni asiko naa ti de, nigba ti awọn olujọsin yoo maa sin Baba ninu ęmi ati ni otitọ; nitori pe iru wọn ni Baba n fę ti yoo maa sin Ọlọrun to ję Ęmi ni otitọ.
Koko to bi ijiroro yii waye laarin obinrin kan to n ba Jesu sọrọ lori nini ibudo ijọsin kan ni pato. Nitootọ o ni oye pe Wooli ni Jesu Ṣugbọn o kọ lati gba pe Atęręrę-kari-aye ni Ọlọrun to tun wa ni ibi kanga ti obinrin naa ati Jesu duro si ti n sọrọ.
Johannu 4:19: Obinrin naa wi fun un pe: Ogbeni, mo woye pe Wooli ni iwọ. Awọn baba wa n sin lori oke yii, ęyin Juu sọ pe Jęrusalemu ni ibi ti o yę ti awa i ba maa sin.
Nitori pe obinrin ara Samaria naa ko mo pe oun wa niwaju Ọlọrun ni asọtęlę naa ṣe jade wa pe: Igba naa n bọ, a ni asiko naa ti de, nigba ti awọn olujọsin yoo maa sin Baba ninu ęmi ati ni otitọ; nitori pe iru wọn ni Baba n fę ti yoo maa sin Ọlọrun to ję Ęmi ni otitọ.
Asiko ayelujara ti ifitonileti fi n kari aye bayii ti mu asọtęlę Jesu ṣę nitori pe ko si ęni to nilo lati rin irinajo lo si ibi Kankan ki wọn to gba iroyin ijọba Orun ninu ọkan wọn nitori pe ęmi ni Ọlọrun; bęę o wa nitosi ju bi a ṣe ro lọkan wa lọ.
Ko si ilę Kankan to mọ ju ilę keji lo niwaju Ọlọrun nigbogbo agbaye; asiko ti to ki a mọ pe ko si ibi ti a ko ti le ba Ọlọrun sọrọ koda, ko ṣe nipasę iroyin tabi ateęjade lati inu ayelujara.
Obinrin ara Samaria naa ko sin Ọlọrun ninu ọkan rę nibi to ti pade Jesu; O n sọ fun Jesu pe ibi kan ni pato ni eeyan ti le sin Ọlọrun nitootọ ni eyi ti Jesu fi ye obinrin naa pe ko ri bęę.
Nigbęyin Jesu baa sọrọ ijọsin tootọ nibi ti obinrin Samaria naa si di ajihinrere. Kanga Jakọbu di ibudo ijọsin tuntun ti ọpọ ti pada wa jọsin nitootọ.
Obinrin Samaria naa fi ikoko omi rę silę, o gba ilu lọ lati lọ pe ero wa pe: E wa wo ọkunrin kan to sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe fun mi. Eni naa a le ję Kristi bi? Wọn si jade kuro ninu ilu naa wa si ọdọ rę (Johannu 4: 28-30)
ẸKỌ TI A KỌ LARA OBINRIN ARA SAMARIA
O han gbangba pe obinrin Samaria ję ęni to gba ęsin pupọ. O maa n lọ sile ijọsin ni Samaria tabi Jerusalemu, Koda, o mo ęsę bibeli kọọkan, Ṣugbọn ko ni ajoṣepọ tootọ pęlu Ọlọrun nitori pe to ba ję bęę ni o yę ko da Jesu Kristi mọ ni kete to ṣe alabapade olugbala. Eyi fihan pe oye rę ninu Ọlọrun ko pọ to.
Aye n yi pęlu ohun gbogbo to wa ninu aye; lasiko ayelujara yii, iwaasu ijọba Ọlọrun le de ọdọ gbogbo eeyan to ba si ọkan rę paya nibikibi, nigbakugba si awọn iwaasu to n jade lati inu imọ ęrọ iroyin tuntun lori ayelujara.
"Itan kan wa nipa ọkunrin kan to gba ęsin pupọ to tun ni gbendeke asiko fun adura gbigba. Lọjọ kan, Ọlọrun fi ara han an ni iṣęju dię ṣaaju asiko adura rę. Ọlọrun sọ fun un nipa oun tikararę, ọkunrin naa si sọ fun Ọlọrun lati duro ki oun gbadura tan ki oun to gbọ ọrọ enu rę”.
Ẹri mi ni pe oore-ọfę Ọlọrun gba mi la lati inu iwaasu ti mo gbọ lati ęnu oniwaasu kan ninu ęrọ amohunmaworan. Ẹnu mi ko le royin iṣę igbala nla ti OLUWA ti ṣe ninu aye mi.
Eyi fi mulę pe nitootọ ni igbagbọ wa nipa gbigbọ ani gbigbọ ọrọ Ọlọrun (Romu 10: 17)
Mo fę fi da ọ loju pe o ṣeeṣe fun ę lati gbọ ohun Ọlọrun ni kęlękęlę ọkan rę nitori ohun to mu ọ le gbagbọ pe owo ti wọ inu banki rę ni kete ti atęranṣę ifitonileti pe owo wọ inu banki rę ba ti dun lori ęrọ alegbeeka naa lo difa fun ę lati gbagbọ pe Ọlọrun le ba ę sọrọ nibikibi, nigbakugba ninu aye.
Ohun ti atęjade Kingdom Blog ti ọtę yii n sọ fun ę ni pe: ĘMI ni Ọlọrun, o ko nilo ayęyę ijọsin ara ọtọ ki o to ni ajoṣepọ pęlu rę ati pe o ṣeeṣe fun ę lati josin fun Ọlọrun bayiii ni ibi ti o wa yii, lai ni lo latilọ si ori oke Kankan ni Jerusalemu, Judea tabi ibikibi ti a ti fi orukọ ya sọtọ fun ijọsin.
O le ni ęgbęfa ọdun ti Ọlọrun ti n duro de awọn Olujọsin ninu iran eniyan. A ko le e tun da Ọlọrun duro mọ lasiko yii nipa lilo awọn ọna ibanisọrọ atijọ nikan mọ bikoṣe pe ki a rin pęlu afęfę ęmi Ọlọrun lati gbe iṣę iwaasu ijọba Ọlọrun ṣe nigbogbo agbaye lọna igbalode pęlu.
Fun apęrę, ọna ibanisọrọ lọna igbalode nipa lilo ayelujara lo fun emi ati iwọ ni oore-ọfę lati jọ maa ba ara wa sọrọ bayii ni eyi ti a gbọdọ tęsiwaju lati fi maa kọ ękọ ninu atęjade Kingdom Blog to ję pepele iwaasu to tọna.
Orin Dafidi 139: 7-12 ni: Nibo ni emi o lo kuro lọwọ ęmi rę? tabi nibo ni emi o sare kuro niwaju rę
Bi emi ba goke lọ si ọrun, iwọ wa nibę; bi emi ba si tę ęni mi ni ipo oku, kiyesi iwọ wa nibę
Emi iba mu iyę-apa owurọ, ki emi si lo joko ninu opin okun; Ani nibę naa ni ọwọ rę yoo fa mi, ọwọ ọtun rę yoo si di mi mu
Bi mo ba wi pe ki okunkun ki o bo mi mọlę, ki imọleę ki o di oru yi mi ka
Nitootọ okunkun kii su lọdọ rę, Ṣugbọn oru tan imọlę bi ọsan; ati okunkun ati ọsan, mejeeji, bakan naa ni fun O.
Ojumọ ire lo mọ loni, o n beere fun ayipada ọkan
Ki ijọba Ọlọrun de ninu ọkan wa, ki ifę rę wa si imuṣę
Ẹ ję ki a gbadura:
Baba wa ti n bę ni ọrun,
Ọwọ ni fun orukọ rę
Ki Ijọba rę ki o de
Ifę tirę ni ki a ṣe ni aye bi wọn ti n ṣe ni ọrun
Amin!!!
Fun ibeere sii:
Ẹ jọwọ kọwe si: igniteinternationalchurch@gmail.com
Ero Ibanisoro: 08121662594