Olukowe: Ayo Awe-Joseph
Onitumo: Dr Olubusola Afolayan
Ijọba Ọlọrun ni atunṣe ati atunto ọkan ęda eniyan ko le pada si eto Ọlọrun fun aye rę lati ibęrę pępę.
Igbesę yii ni i ṣe pęlu ajọṣepọ tabi adapọ ọrun ati aye; eeyan ati angęli lasiko ti wọn ba gbe Ọlọrun soke nipa gbigbọran si aṣę rę gęgę bii ti atetekọṣe.
Gbigbadura pe ki ijọba Ọlọrun de dabi bibeere pe ki Ọlọrun yọ gbogbo awọn oniṣę ibi kuro ni aye Ọlọrun to da (pęlu ireti, a ko si ninu awọn eniyan wọnyii).
Jesu wa mu IFĘ Ọlọrun ṣę ni nipasę sisan ębọ idiyele nla pęlu ęję rę lati ra eniyan pada. Idi yii gangan lo ṣe ku lori igi agbelebu.
Gbogbo wa la mọ pe lati igba ęṣę ninu ọgba Edeni ni awọn eniyan ti n bimọ ninu irora nla titi di asiko yii ni eyi ti tọkunrin tobinrinn ke irora nla ninu ęmi ki wọn le di ọmọ Ọlọrun pada.
Iwe Romu 8: 22-25 ṣalaye pe:
Nitori ireti ni a fi gba wa la; Ṣugbọn ireti ti a ba ri kii ṣe ireti; nitori ta ni ireti ohun ti a ba ri?
Ṣugbọn ti awa ba n reti eyi ti a ko ri, nję awa n fi suuru duro de e.
Erongba wa ni Ignite Internatiọnal Christian Church ni ki a ba Ọlọrun dowopọ nipa iṣęda nipaṣę Kristi to n gbe ninu wa. “AWỌN OLUGBE AYE TUNTUN”
Romu 8: 19 ni pe:
Nitori ifojusọna ti ęda n duro de ifihan awọn ọmọ Ọlọrun
Kini Awọn Abuda Adamọ Awọn Olugbe Aye Tuntun?
* Wọn yoo ję ęda eniyan ti ero ọkan wọn, ifę inu wọn, ati ọpọlọ wọn yoo wa ni iręlę niwaju Ọlọrun ti wọn yoo si maa gbọran si aṣę Ọlọrun
* Gęgę bi ọdọlangba, awọn eniyan wọnyii yoo gbe igbe aye iwa mimọ, wọn yoo pa ara wọn mọ gęgę bi agọ ęmi mimọ.
* Gęgę bi obi, wọn yoo tọ awọn ọmọ wọn ni ilana Ọlọrun nitori pe wọn mọ pe Ọlọrun n reti ki wọn fi ibęru oun tọ awọn ọmọ wọn.
* Gęgę bii ọkọ to ję bale ile, wọn yoo fęran iyawo wọn tọkantọkan, wọn yoo fi suuru maa ba wọn lo pọ nigba gbogbo.
* Gęgę bii iyawo, wọn yoo ni itęriba fun awọn ọkọ wọn, kii ṣe bii ọmọ abę rę bikoṣe bii alajumọṣiṣępọ ti wọn jọ n tọ awọn ọmọ ni ilana Ọlọrun.
* Gęgę bii akękọọ, wọn yoo mọ iwe, wọn yoo si fi ọkan si ękọ wọn. Wọn yoo gbọ lati ọdọ ęmi mimọ ti yoo ję ki wọn maa ni ọpọlọ pipe lati ṣe agbekalę awọn nkan ara tuntun ti yoo ję ki aye dun un gbe fun ọpọlọpọ iran sii.
* Gęgę bii Oloṣelu ati oṣiṣę ijọba, wọn yoo bęru Ọlọrun ninu iṣejọba wọn. Pęlu ifę ara ilu ati ootọ inu ni wọn yoo fi maa dari awọn ti wọn n ba ṣiṣę laidalę awọn oludibo nitori wọn mọ pe awọn yoo jabọ fun Ọlọrun lọjọ kan.
*Awọn Olugbe aye tuntun yii to ję ologun ati agbofinro yoo bu ọla fun Ọlọrun lęnu iṣę wọn nipa ihuwasi akin ti wọn a maa hu laigbọjęgę.
* Gęgę bii olokowo, wọn yoo ję olootọ lęnu okowo wọn lailo oṣuwọn buruku; pęlu oore-ọfę ni wọn yoo fi ję adun aye lęnu okowo wọn
*Gęgę bii olutọju awọn eniyan, ęmi mimọ yoo ran wọn lọwọ lati sin gbogbo ęda alaaye tọkantọkan.
*Wọn yoo ję akọṣęmọṣę lęnu iṣę oojọ wọn bii awakọ ofurufu, olukọni, oniṣegun oyinbo, ati bęę bęę lọ to n da ęmi mọ yatọ nitori ti wọn n gbọran si Ọlọrun lęnu lati doola ęmi nigba gbogbo.
Ọlọrun ni eto to n lọ lọwọ fawọn olugbe aye tuntun yii.
O maa gba gbogbo awọn to n huwa ęṣę atawọn ti ko mu inu rę dun nipa iwa ọwọ wọn danu gęgę bi o ṣe ri nigba aye Noa.
Matteu 24: 36-39 fidię mulę pe nigba naa, awọn eniyan n jęun, wọn n mu, wọn n gbe iyawo, wọn tun n fi iyawo fun ọkọ ki Noa to wọ inu ọkọ. Koda, wọn ko mọ titi ikun omi fi gbe wọn lọ.
Ki Ọlọrun ka wa yę mọ awọn olugbe aye tuntun; Ki Ijọba rę de ninu ọkan wa ati ninu aye wa.
Fun ibeere:
Ẹ jọwọ kọ iwe si: igniteinternationalchurch@gmail.com
Ero Ibanisoro: 08121662594