Olukowe: Ayo Awe-Joseph
Onitumo: Dr Olubusola Afolayan
Ni ọdun dię sęyin mo lọ si ilu Ibadan (Naijiria) ni eyi ti mo ni lati gba itọni lọwọ ęrọ ayęlujara to n ṣapejuwe opopona ti wọn n pe ni ‘Google Map’ ki n to le mọ ọna de ibi ti mo n lọ ni pato.
Nigba to ya, ęrọ ayelujara ’google map’ yii ko ba ri ami to nilo mọ to yę ko fi dari irinajo mi ni mo ba yara beee ọna lọwọ awọn to n rin lọ loju titi ti wọn si juwe ọna ibi ti mo n lọ fun mi ni pato.
Mo mọ pe ọpọ ninu wa lo ti sọnu nigba kan tabi omiran ti a si ti ni lati beere apejuwe lọ si ibi ti a n lọ lọwọ awọn ero oju titi.
Lęyin o ręyin, ęrọ ayelujara google map pada gbe mi de ibi ti mo n lọ to si ni pe “O ti de ibudo ti o n lọ”
Ko si ęni to le mu ọ de ibudo kan laiję pe oun gangan ti de ibę ri tęlę:
Nigba ti Tọmasi beere ọna lọwọ Oluwa pe awọn ko mọ ibi ti o n lọ ninu iwe Johannu 14: 5-6 ni Jesu dahun pe: Emi ni ọna, otitọ ati iye, ko si ęni to le de ọdọ Baba bikoṣe nipasę mi.
Tọmasi ję eniyan ti iwa rę yatọ laarin awọn ọmọ ęyin Jesu Kristi Oluwa wa. O ję ęni to n sọ ohun to ba n ro ni ọkan rę laipa irọ bii ọmọde. O beere ibeere ti ko wọpọ ni eyi ti mo gba pe ko bi Oluwa ninu rara nitori mo mọ pe Jesu naa ma fęran Tọmasi fun igbooya rę.
Ni gbolohun kan pere ni Jesu Kristi OLUWA fi dahun ibeere nla lori ibi ti a n lọ eyi ti Tọmasi beere. Jesu dahun pe: EMI NI ỌNA TO LỌ SI ỌDỌ BABA.
Mo mọ pe lati asiko naa lọ ni irinajo ati ibudo ti awọn ọmọ ęyin n lọ ti han sii fun Tọmasi ati awọn ọmọ ęyin Jesu to ku. Bakan naa ni wọn mọ ỌNA lati de ibi ti wọn n lọ naa nipasę Jesu Kristi to ję ATỌNA fun wọn.
Asiko ti to ki ọpọlọpọ kristięni beere lọwọ awọn adari ile ijọsin wọn sii nipa ibi ti wọn n lo. O ṣe Pataki lati beere ibeere nla yii paapaa bayii ti a ti mọ pe oun ni ọna si ọdọ BABA.
O hande pe awọn miran kan n tęle adari ile ijọsin wọn bii afọju ni lati ọdun pupọ ṣęyin laini erongba ati ibudo igbęyin ni pato lọkan wọn. Koda, awọn miran n woye lori ibi ti wọn wa bayii nitori wọn ko fęe mọ bi wọn ṣe de ibe.
Ko ṣeeṣe fun eni to n rin lai ni ibudo igbęyin ni pato lati mọ ibi ti o de duro rara; koda iru ęni bęę kọ le mọ igba to de ibę.
Awọn miran ti lugbadi ỌNA alumọkọrọyi nipasę awọn igbesę ati eto ti ko yę ti wọn ti tọwọbọ ninu irinajo wọn. Wọn ti ṣe paṣipaarọ bi ohun iṣere ọmọde fun awọn miran ninu irinajo lọ si ọdọ BABA yii.
Ninu aye ti a wa yii, ọpọ ninu awọn adari ijọ gbọn pupọ ti ęnu wọn si dun bii ti ajakara, ọpọ ni ębun ati talęnti to yatọ ni eyi ti wọn fi n pero to pọ sinu ijọ wọn lorukọ Jesu Kristi Ṣugbọn ti ibudo igbęyin wọn kii ṣe ọdọ BABA.
Awọn miran bęrę irinajo naa lọna to yę Ṣugbọn wọn ya kuro nibę nitori pe tooro ni ỌNA NAA. Awọn miran fi awọn to n tęle wọn sinu igbekun nipa lilo arekereke lati ko ọrọ jọ fun ara wọn lorukọ Jesu ni eyi ti wọn ti sọ awọn eniyan di onworan ninu irinajo aye wọn.
Matteu7: 15-20 ni pe: Nipasę eso wọn ni a o fi mọ wọn
O yę ki n ṣalaye nibi pe ko si ohun to buru ninu ki eniyan fęran adari rę tabi ko maa bu ọla fun olori ijọ rę Ṣugbọn ọmọlęyin Jesu nitootọ to ję adari gbọdọ maa fi ye wọn pe ifę ati gbogbo ọla naa gbọdọ lọ si ọdọ BABA ki awọn ero ma lọ sọ awọn ojiṣę Ọlọrun di oriṣa akunlębọ
Ọlọrun da ohun gbogbo ni aye yii fun igbadun, ọla ati iyin ara rę ni; kii ṣe ki adari kan fi sọ ra rę di oriṣa lọwọ wọn ọmọ ijọ rę.
Iṣę iranṣę ti a gbe le wa lọwọ ni lati mu awọn eniyan ninu aye pada wa si iwaju Ọlọrun wọn. Gbogbo ipo, ọgbọn, talęnti, ębun ati oye to wu ki olori ni laye gbọdọ ję fun ogo Ọlọrun ati lati da awọn eniyan pada sọdọ Ọlọrun to da wọn ni, ki wọn le fę Oluwa Ọlọrun wọn lọkan wọn nitootọ.
Gbogbo irinajo ti eeyan ba n rin ni ỌNA NAA nipasę ijọ Ọlọrun ki ijọ Ọlọrun ti eeyan ti n jọsin gbọdọ mu eeyan naa de ọdọ BABA. Ijọ Ọlọrun, ębun awọn olukọni, Wolii, Apọsteli, Ajihinrere gbọdọ maa fi ye awọn eniyan pe ọdọ BABA ni ki wọn pari irinajo wọn si nikęyin. Ikọni-ki-ikọni ti ko ba ti mu ęni de ọdọ Baba ję ibọriṣa ati ọna lati ko ọrọ jọ to si ṣe lodi si ijọba Ọlọrun.
Isaiah 35: 8 sọ pe opopona kan yoo si wa nibę, ati ọna kan, a o si ma a pe e ni ọna iwa mimọ; Alaimọ kan ko ni kọja nibę, nitori pe oun yoo wa pęlu wọn, awọn ero ọna, bi wọn tilę ję ope, wọn ki yoo sii.
Okowo Ijọ ję okowo Ijọba Ọlọrun.
Ki ifę Ọlọrun ṣę ninu ọkan gbogbo, bi o ti n ṣę ni Ọrun.
Fun ibeere: igniteinternationalchurch@gmail.com
Ero ibanisoro:08121662594